DiscoverYoruba.com is your one-stop for embracing Yoruba culture, entertainment, and history unfolding.

Àwọn Ààyè Ìfàmọ́ra Fún Àwọn Arìrìn-Àjò Ní Ilẹ̀ Yorùbá (Tourists Attraction places In Yoruba Land)

Sharing is encouraging! If you enjoy reading this article, kindly consider sharing it with your friends. Thanks!


Ọrọ Iṣaaju (Introduction)

Gúúsù iwọ̀-oòrùn jẹ́ agbègbè tíí arìrìn-àjò kò gbọdọ̀ mádèé tóbáwá bojúwo Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Arìnrìn-àjò sá gbọdọ̀ dé agbègbè yíì ni lórí ìrìn-àjò wọn. Gúúsù yìí jẹ́ òkan lára àwon gúúsù mẹ́fa tó wà ní orílẹ̀-èdè yìí, tó sì jẹ́ ilé fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀ṣun, Ògùn, Òndó, Èkìtì, àti Èkó. Ìpínlẹ̀ mẹ́fà yíì kún fún àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì àti nkàn ìwòye tó yani lẹ́nu púpọ̀ káàkiri. Asì máa mẹ́nuba díẹ̀ nínúu àwọn ààyè ìfàmọ́ra fún àwọn arìnrìn-àjò wá sí ilẹ̀ Yorùbá wọ̀nyìí.

Tourists Attraction places In Yoruba Land (Àwọn Ààyè Ìfàmọ́ra Fún Àwọn Arìrìn-Àjò Ní Ilẹ̀ Yorùbá)

1. Ìtúra-Orílẹ̀ Ti Ọ̀yọ́ Àtijọ́ Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (Old Oyo National Park)

Ìtúra-orílẹ̀ ti ọ̀yọ́ àtijọ́ táa mọ̀ṣi ‘Old Oyo National Park’ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ààyè ìfàmọ́ra fún arìrìn-àjò tó ní pàtàkì jùlọ ní ilẹ̀ Yorùbá. Ààyè yìí wà láàrin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Ìpínlẹ̀ Kwara. Ààyè yìí ṣì bo agbègbè kan tójẹ́ igbó kìjikìji èyí tófẹ̀ rẹpẹtẹ. Alè bẹ ààyè yìí wò láti Ṣakí, Ìséyìn, Ìgbòho, Tedé, àti Ìgbẹ́tì ní ìpínlè Ọ̀yọ́. Ààyè yìí kún fún oríṣiríṣi ewéko àti ẹranko.

Nínú àwọn ẹranko wíwọn tówà ní ààyè yìí lati rí àwọn ìnọ̀kí, ọ̀bọ aláwọ̀ pupa, ẹtu oríṣiríṣi, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ẹranko yíì pọ̀ tósìjẹ́pé akòle kàwọ́n tán. Bí ẹranko ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ewéko oríṣiríṣi náà tún pọ̀ níbẹ̀. Àwọn àpáta ràbàtà tótipẹ́ àti àwọn ihò-ilẹ̀ tún pọ̀ sí ìpẹ̀kun àríwá ààyè yìí. Àwọn àpáta àti òkè tótóbi yìí wà fún òkè-gígùn fún ìgbafẹ́ àwọn olùbẹ̀wò.

 Ìtúra-Orílẹ̀ Ti Ọ̀yọ́ Àtijọ́ (àwòrán láti afrotourism.com)

Ìtúra-Orílẹ̀ Ti Ọ̀yọ́ Àtijọ́ (àwòrán láti hotels.ng)

2. Òkè Olúmọ Ní Abéòkúta – (Olumo Rock)

Òkè Olúmọ wà ní ìlú Abéòkúta àtijọ́ ní ìpínlè Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òkè yìí gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ààyè ìfàmọ́ra fún àwọn arìnrìn-àjò wá sí ilẹ̀ Yorùbá. Ìtàn tó wà lẹ́yìn òkè yìí túnbọ̀ jẹ́ kó gbajúmọ̀ síi. Ní ìgbà tótipẹ́, àwọn Ẹ̀gbá fii òkè yìí ṣe ìdáàbòbò ní ìgbà ogun; wọ́n múu gẹ́gẹ́ bíi odi táwọn ọ̀tá kò le gorí.

Ní ọdún 2006 ni wọ́n tún òkè yìí ṣe láti di ààyè ìfàmọ́ra fún arìrìn-àjò. Wọ́n fi àwọn nkàn amáyédẹrùn kún òkè yìí. Àwọn nkàn bii orísun omi ńlá, ilé ọ̀nà, ilé oúnjẹ, àtẹ̀gùn, àbágùnkè ẹlẹ́sẹ̀ àti àwọn nkàn mère mère míràn niwọ́n fi kún òkè yìí. Àwọn nkàn àfikún yìí túnbọ̀ jẹ́ kí òkè gígùn jẹ́ dídùn fún olùbẹ̀wò àti láti gbafẹ́. Láti ṣe àbẹ̀wò sí òkè ayanilẹ́nu yìí, olùbẹ̀wò máa nílò láti san owó-ìwọlé kékeré tíkòga jara lọ.

Àwọn olùfihàn ìrìn-àjò púpọ̀ ló wà nílẹ̀ láti ran àwọn olùbẹ̀wò lọwọ láti gun òkè yìí, àti láti jẹ́ kíwọ́n mọ ìtàn tówà lẹ́yìn òkè yìí. Bí àwọn olùbẹ̀wò bá ṣeńgun òkè yìí ni wọ́n máa rí àwọn ọ̀dà-kíkùn mère mère, ati oríṣiríṣi ère gbígbẹ́ tó kún ààyè yìí. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n tún máa rí àwọn olùgbé arúgbó kọ̀ọ̀kan tí wón máa ṣàdúrà lójú ọ̀nà. Gbogbo àwọn nkàn yìí ńṣe àfihàn àwọn àṣà, ìtàn, àti, ìṣe tósomọ́ ààyè yìí. Láì ṣe àdínkù, ààyè yìí jẹ́ ibìkan tóogbọdò dé gẹ́gẹ́ bíi arìrìn-àjò wá sí ilẹ̀ Yorùbá.

Òkè Olúmọ (àwòrán láti travelgeniuz.com)

3. Òkè Ìdànrè Ní Àkúrẹ́ (Òkè Ìdànrè Hills)

Àkúrẹ́ jẹ́ ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Òndó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ìlú yìí jẹ́ ilé sí ààyè ìfàmọ́ra tí amọ̀ sí Òkè Ìdànrè. Òkè yìí wà ní egbèrún-mẹ́ta ẹsẹ̀ sí ìpele òkun. Àwọn nkàn méèrírí tó wà ní agbègbè yìí pọ̀ lọ́pọ̀ lọ́pọ̀. Nínú wọn lati ri ààfin Ọwá, ojúbo òòsà, kọ́ọ̀tù àtijọ́, ẹsẹ̀ bàtà Agbóògùn, omi Aópàrá, àti àwọn ààyè ìsìnkú kọ̀ọ̀kan. Òkè yìí tún jẹ́ ààyè àjogúnbá fún ẹgbẹ́ UNESCO láti ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹwàá, ti ọdún 2007.

Ní àbáwọlé ìlú Ìdànrè àti òkè yìí lati rí igi àtijọ́ kan táamọ̀sí Igi Ìràyé. Níbè náà lati rí àwọn ewéko àti eranko oríṣiríṣi eléyìí tómú ààyè yìí jẹ́ ìyàlẹ́nu. Àwọn àdán tó pọ̀ púpọ̀ ló wà ní ààyè yìí tófijẹ́pé wọ́n máan ṣe ọdún àdán lọ́dọọdún láàrin àwọn olùgbé agbègbè yìí. Àwọn ọ̀bọ àti àwọn eranko aláìnírù kaan táamọ̀ sí ‘hyrax’ túnpọ̀ lágbègbè yìí, pàápàá jùlọ káàkiri Òkè Orósùn. Mélòó mélòó àwọn eléré ni wọ́n ti fi ààyè yìí ṣe ààyè ìyàwòran fún oríṣiríṣi eré ìbílẹ̀.

Òkè Ìdànrè (àwòrán láti commons.wikimedia.org)

Òkè Ìdànrè (àwòrán láti guardian.ng)

4. Ìsọ̀sílẹ̀omi Ẹrin-Ìjẹ̀sà Ní Ìpetu-Ìjẹ̀sà (Erin ijesa waterfall)

Ìsọ̀sílẹ̀omi yìí jẹ́ òkan lára àwon ààyè tí àwọn arìnrìn-àjò ògbọdọ̀ mádèé tí wọ́n bá ṣe àbẹ̀wò sí ilẹ̀ Yorùbá. Ààyè yìí wà ní Ìpetu-Ìjẹ̀sà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ẹrin-ìjẹ̀sà tí a tún le pè ní ìsọ̀sílẹ̀omi Olúmirìn fi ogójì kìlómítà jìnà sí ìlú ifẹ̀, tí ósì fi mẹ́tàdínlógójì kìlómítà jìnà sí ìlú Àkúrẹ́ ní ìpínlẹ̀ Òndó.

Ààyè yìí jẹ́ ààyè ìfàmọ́ra fún arìrìn-àjò nítorí omi tón sàn sílẹ̀ láti orí òkè onípele méje yìí. Láti dé òkè téńté ìsọ̀sílẹ̀omi yìí, olùbẹ̀wò máa nílò láti gun àbágùnkè ẹlẹ́sẹ̀ fún ìgbà díẹ, ósì máa nílò láti mú òkè yìí gùn pẹ̀lú ọwọ́ àbí nkàn ìgùn fún ìgbà díẹ. Gígùn wà lára nkàn tójẹ́ kíí àmójúbà jẹ́ dídùn.

Ìtàn tó wà lẹyìn ìsọ̀sílẹ̀omi yìí jẹ́kan tó yanilẹ́nu. Mímójúba òkè onípele méje yìí àti ìsọ̀sílẹ̀omi yìí ní ìpele kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìfàmọ́ra àti ohun ìyàlẹ́nu fún ẹnikẹ́ni. Ní ìtẹ̀síwájú, ọjà ẹní-híhun wà nítòòsí agbègbè yìí.

Ìsọ̀sílẹ̀omi Ẹrin-Ìjẹ̀sà (àwòrán láti pulse.ng)

Ìsọ̀sílẹ̀omi Ẹrin-Ìjẹ̀sà (àwòrán láti pinterest.com)

5. Ọ̀pá Ọ̀rànmíyàn Ti Ilé-Ifẹ̀ (Oranmiyan’s Shaft)

Ní ilé-ifẹ̀, èyí tó wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà latirí Ọ̀pá Ọ̀rànmíyàn yìí. Ọ̀pá yìí jẹ́ òkúta pẹlẹbẹ ìrántí tówà ní ìdúró, tósì ga sókè gogoro. Ọ̀pa yìí túnbọ̀ níí àwọn àmì kan eléyìí tófi ìtàn tó wà lẹ́yìn ọ̀pá náà hàn.

Ìtàn táadébá láti ayé dáyé ni pé ọ̀pá yìí jẹ́ gbígbékalẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ọ̀rànmíyàn Ọmọlúwàbí. Ọ̀rànmíyàn jẹ́ òkan lára àwon ìdílé Òdùduwà tójẹ́ olùdásílẹ̀ ẹ̀yà Yorùbá. Ọ̀rànmíyàn sì tún jẹ́ ọ̀ọ̀ni pàtàkì àtijọ́ isí ilé-ifẹ̀.

Ọ̀pá Ọ̀rànmíyàn yìí niwọ́n mọ sí dèèdé ibi tí Ọ̀rànmíyàn ti papòdà. Nkàn ìyàlẹ́nu tó wà ní ààyè yìí nipé àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ṣe àwọn ìwádìí kan láti fimulẹ̀ pé ọ̀pa yìí tiwà ní mímọ síwájú ayé Òdùduwà fúnra rẹ̀. Nígbà tí àwọn olùbẹ̀wò bá ti gbọ́ ìtàn Ọ̀rànmíyàn, wọ́n máa kọ́ pé Òdùduwà jẹ́ Aláàfin Ọ̀yọ́ àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó fìdí ìlú náà múlẹ̀ ní ọdún 1170.

Ọ̀pá Ọ̀rànmíyàn (àwòrán láti commons.wikimedia.org)

Ọ̀pá Ọ̀rànmíyàn (àwòrán láti oldnaija.com)

Ìparí(Conclusion)

Níparí, ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ agbègbè kan táafimúlẹ̀ sí gúúsù iwọ̀-oòrùn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ilé sí ìpínlè mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nínú ìpínlè kọ̀ọ̀kan lati máa ri oríṣiríṣi àwọn ààyè ìfàmọ́ra fún àwọn arìnrìn-àjò wá sí ilẹ̀ yìí, táasì mẹ́nuba díẹ̀ nínú àwọn ààyè yìí.

Sharing is encouraging! If you enjoy reading this article, kindly consider sharing it with your friends. Thanks!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *