DiscoverYoruba.com is your one-stop for embracing Yoruba culture, entertainment, and history unfolding.
Ọrọ Iṣaaju (Introduction)
Ní àsìkò tí ó ti ṣáájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn míràn yàtọ̀ sí ilẹ adúláwọ ni igbagbọ wípé ilẹ̀ adúláwọ kò ní ìtàn àṣà àti ọlájù tí ènìyàn lè kọ ẹ̀kọ́ nípa rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọwè pàápàá jù lọ ní ìwọ oòrùn (Westerners) lágbáye náà jẹri sí wípé àwọn ẹ̀yá aláwọ̀ dúdú ó jamọ ń kankan àti wípé ènìyàn yẹpẹrẹ níwọ̀n pẹlu kí ó tó dì wípé àwọn òyìnbó aláwọ̀ fún fún wá sí ilẹ adúláwọ.
Lọdọ àwọn òyìnbó, n kàn pàtàkì tí wọn ṣe àkọsílẹ̀ rẹ ni ohùn tí ó ṣẹlẹ̀ nígbàti àwọn òyìnbó ẹgbẹ́ wọn ń bẹ ní ilẹ adúláwọ pàápàá julọ nígbàtí àwọn ará ìhà-àríwá ṣe àwárí ilẹ̀ adúláwọ (European explorations), owó ẹrú (Slave trade), ìṣe ìhín réré nípa Jésù (Christian missionary works), ìgbà yíyí ìṣejọba padà (Colonial rule) àti bẹẹ bẹẹ lọ.
Ìṣe àríwoye ilẹ̀ Aláwọ̀ dúdú fún àwọn òní kòrírà òyìnbó aláwọ̀ fún fún (Prejudiced Observers), wọ̀n ṣe àfi tí ọ̀rọ̀ wọn wípé ilẹ̀ adúláwọ kò lé ní ọlájù kan gbòógì tí ó lé mú ọgbọ́n wá.
Ìrórí wọn dá lórí ìrísí àyíká ilẹ̀ adúláwọ (faulty premises) àti wípé ilẹ̀ adúláwọ ṣe afẹku kíkọ àti kíkà, àti wípé wọn kò ní ìwé (Books), kálámù (Pen) àbí ọna míràn fún àkọlé ohun kohun(No means of recording), kí kọ n kan gan-an ni wọn ní igbagbo sì gẹ́gẹ́bí ìtàn, àṣà àti ọlájù tí ènìyàn lè ní.
Ní ọdún 1920s, fún àpẹẹrẹ, ẹni ọwọ́ olùkọ́ kán (A.R Newton) sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ wípé ” ìtàn bẹ̀rẹ̀ ni ìgbátí ọmọ ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sì ṣe àkọlé nkan” ó tún tẹ síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ wípé ilẹ̀ adúláwọ kò ní ìtàn, nítorí wípé báwoni àṣe lè rò wípé kí àwọn ìran yẹpẹrẹ ó kọ ìtàn nípa wọn silẹ, igbagbo wọn ní wípé àlákòbẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ni ilẹ̀ adúláwọ, ìtàn nípa wọn bẹ̀rẹ̀ nígbàtí àwọn òyìnbó aláwọ̀ fúnfún dé (Arrival of Eurocentric Scholars).
Ó hàn wípé ilẹ̀ Íjíbítì (Egypt) ó sì nínú màápu (Map) Newton, nítorí ìdí èyí kò gbọ nípa hiriroglyphic (Hieroglyphics). Kìí se Newton ní kàn ní kò mọ nípa rẹ nínú àwọn ọmọwè ìhà-àríwá.
Ìdáhùn rẹ lórí ìtàn ilẹ̀ adúláwọ nígbà tí wọ́n fún wọn ní ìyàndá ní ọdún 1963 láti kó nípa ilé adúláwọ, Professor Huge Trevor-Roper tí ilé ẹ̀kọ́ gíga Oxford University sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ wípé
” Òṣé ṣe ni ọjọ iwájú kí ó ní àwọn ìtàn nípa ilẹ adúláwọ láti kọọ, ṣùgbọ́n ní báyìí wọn kò ní ìtàn kánkán, ìtàn nípa àwọn òyìnbó aláwọ̀ fúnfún nìkan ló ń bẹ ní ilẹ adúláwọ, òkùnkùn (Africans are in darkness) ni èyí tó kú, àti wípé òkùnkùn ó sì lára ìtàn, a kò lè máà mú inú ara wá dùn pẹlu ìtàn àwọn ẹ̀yá ti wọn ko ni ìtumọ̀ kankan tí wọn kàn kò ará wọn jọ sí ẹgbẹ́ kàn ayé” .
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ àbùkù nípa ìran aláwọ̀ dúdú láti ẹnu (Professor Huge Trevor-Roper) àwọn ọjọgbọ́n ilẹ̀ adúláwọ (African Scholars) parapọ̀ láti dá ọ̀rọ̀ náà nù, wọn gbà wípé ọ̀rọ̀ tí ó jìnnà réré sí òótọ́ ni irú ọ̀rọ̀ bẹ, wọn wípé Iròri tìrẹ nípa ìran adúláwọ nìyẹn ṣùgbọ́n Iròri yẹn ó fìdí òótọ́ múlẹ̀.
Ǹjẹ́ o ti lẹ bá ọpọlọ pípé mú kí ènìyàn gbà wípé ilẹ̀ adúláwọ kò ní ìtàn síwájú kí àwọn ìran aláwọ̀ fúnfún tó dé? Àbí ó bá ọpọlọ pípé mú kí ènìyàn ṣe afi tí àṣà, ọlájù àti ìtàn sì ibì ìwé kíkọ àti kíkà nìkan? Kò sí tàbí ṣùgbọ́n gbogbo eléyìí takò ìlàkàyé (Products of intellectual dishonesty).
Ìtàn Ilé adúláwọ àti ìran adúláwọ jẹ ohùn tí àwọn ọmọwè ìhà-àríwá (Eurocentric Scholars) fọ lójú nípa òtítọ́ rẹ (Blind spot experience).
Ipari (Conclusion)
Kí bajẹ wípé òtítọ́ ni ilẹ̀ adúláwọ kò ní ìtàn, ọlájù ati àṣà ni, njẹ báwo ni ó ṣe rọrùn fún ìran aláwọ̀ dúdú láti tọju ìtàn, àṣà àti ọlájù wọn olówó ìyèbíyé (Rich cultural activities) títí dí òní.
Kíkọ àti mimọ nípa àṣà ìtàn àti ọlájù wà dí ẹtọ fún oníkálukú láti mọ kí a bá lé fì idi irọ àwọn òyìnbó múlẹ̀ nípa irori wọn lórí ilẹ̀ adúláwọ (To debunk the erroneous impression and propaganda of the west). Àti wípé ó máa ṣé itokasi fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ (Students) àti àwọn oníwàdi (Researchers) láti ni imọ ìjìnlẹ̀ lórí ìtàn, àṣà àti ọlájù ilẹ̀ adúláwọ.
Títọju àṣà kò dá lé kíkọ́ sílẹ̀ lásán, àlè ṣe àkọsílẹ̀ rẹ (Written), tàbí kí ó wà ní ọkàn-àyà àwọn ènìyàn (Mind of the people), a sì tún lè mọ pẹlu rírí àwọn ǹkan ńṣẹ báyé (Artefacts). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọna lọ́wa fún ọmọwè láti mọ àṣa, ìtàn àti ọlájù ilẹ̀ adúláwọ ṣùgbọ́n mẹrin tí ó gbajumọ ni; bíbá ará ẹni sọ̀rọ̀ (Oral tradition), imọ nípa ohun àtijọ́ (Archaeology), kíkọ silẹ (Written), àti èdè sísọ (Linguistic). Àlàyé nípa àwọn ọ̀nà wọ̀nyí ń bò ni ọjọ iwájú. Ẹ máa bá wa ká lọ.
Dr. S.Ademola Ajayi. Linguist at Adekunle Ajasin University of Akungba Akoko ondo state Nigeria.
My clique on FB would really like your blog. Mind if I show it to them?
Hello,
No i don’t. please go ahead