DiscoverYoruba.com is your one-stop for embracing Yoruba culture, entertainment, and history unfolding.
Definition of Orisa in Yoruba religion
Òrìsà ní Ilẹ̀ Yorùbá jẹ ẹ̀mí tí Olódùmarè rán sí ilé ayé fún ìtọ́ni sónà àwọn ẹ̀dá pàápàá jùlọ ẹ̀dá ènìyàn, nípa bí a ṣe lè gbé ìgbésí àyè irọrun. Atìpè, nínú àṣà (Culture) Yorùbá, ìtumọ̀ òrìṣà ní orí-ṣá ( Head hand-picked it).
Ètọ́ ni fún ènìyàn láti máa bọ wọn. Ohùn tí ó fi ìdí múlẹ̀ nínú ẹsin (in Yoruba religion) ìran Yorùbá ni wípé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òrìṣà tí ń bẹ ní ọ̀run gẹ́gẹ́bí irúnmọ́lẹ̀, kí Olódùmarè tó fí wọn ránṣẹ wá sí ilé ayé, àwọn òrìṣà míràn tì wá gẹ́gẹ́bí ènìyàn alábàrà ṣùgbọ́n wọn di òrìṣà láti àrà isẹ tákúntákún tí wọn ṣe nígbà tí wọn bẹ ní orílẹ̀ ayé.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òrìṣà yí ní wọn bẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ayé látàra owó ẹrú (slave trade) tí àwọn òyìnbó aláwọ̀ fún fún (White men) sì nifẹ sì láti máa ṣe jọsin fún àwọn òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá. Aléṣe àlá ba pàdé bíbọ òrìṣà ní àárín àwọn Bini ni gúúsù orílè èdè Nàìjíríà (Southern Part of Nigeria), bẹẹni ni Togo, Ghana, Benin àti bẹẹ bẹẹ lọ.
Ìjọsìn fún òrìṣà nííṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àwọn ìran aláwọ̀ dúdú, gẹgẹbi àṣẹ rí nínú ọ̀rọ̀ ọjọ́gbọn John Mason, ẹniti ó kọ ìwé (Black God’s) Ọlọ́run àwọn ènìyàn dúdú.
Ọ̀nà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní o wá fún ìṣe dálẹ bíbọ òrìṣà, àwọn abọ̀rìṣà ní ìgbàgbọ́ wípé àṣẹda tí ǹjẹ́ Elédùmarè tàbí Ọlọ́run (Almighty God), òrìṣà (gods), akànda ẹdá (Legends), àwọn bàbà ńlá wọn (Ancestors ), àwọn igi tàbí ẹranko (Plants or Animals). Ìgbàgbọ́ Yorùbá (Yoruba religion) ni wípé àwọn wọ̀nyí ni wọn só ilé ayé róó tí ó sì ṣé pàtàkì kí a máa bọ wọn.
Yorùbá ni ìgbàgbọ́ wípé ohùn gbogbo ni ó ní ìré àti ibí (Good and Bad), tí kò sì òhun tí ó pamọ fún méjèèjì, èyíinì wípé tí ibí tirè Ládánì dá ilé ayé. Fún àpẹẹrẹ àwọn adifála má ń lò owó ẹyọ tàbí ọpẹ̀lẹ́ láti fí wó ohùn tí òrìṣà ń bèrè bóyá ibi tàbí ire ń bẹ nínú nkan, wọn a sì tún máa béèrè fún òhun ẹbọ.
Àwọn ẹ̀yà Yorùbá (Yoruba Tribe) ní ìgbàgbọ́ wípé irínwó lè ní ẹyọ kan (401) ni gbogbo òrìṣà tí onbẹ ní ilé ayé, àwọn ẹlòmíràn sì ni ìgbàgbọ́ wípé ojú irínwó àti ẹyọ kan lọ, wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wípé ìyè òunká tí ènìyàn bá lè fi ọkàn rẹ ró pẹ̀lú ẹyọ kan ( uncomfortable plus one) náà ni ìyè òrìṣà tí óń bẹ, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn gbà wípé ìyè wọn jẹ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́rin (700) tàbí ẹgbẹ́je (1400).
Ìgbàgbọ́ àwọn abọ̀rìṣà (Idol worshipers) ni wípé bí ènìyàn bá ṣé bọ oriirẹ náà ní orí yíò ṣe gbèè, eléyìí ń túmọ̀ sí wípé bẹẹ ní yíò ṣe ni àṣeyọrí sí. Àwọn Yorùbá fi ìdí bíbọ àwon akànda ẹ̀dá kàn lè lẹ gẹ́gẹ́bi àwọn jàgùn jàgùn (Warriors), ọba (Kings), àti àwọn tí wọn ṣe iṣẹ́ dálè ìlú (Founders of cities), wọn a máa ṣe àjọyọ (Celebrations) lẹhin ikú àwọn, wọn yìí wọn a sì máa bọ wọn gẹ́gẹ́ bí òrìṣà, wọn ní ìgbàgbọ́ wípé àwọn ènìyàn wọn yí o kù, ṣùgbọ́n wọn ṣì ipò padà ní. Bíbọ àwọn òrìṣà miran kojú láàrin àgbò ilé kan lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn miran jẹ òrìṣà gbogbo ìlú lapapọ.
Ìpín òrìṣà ní ilẹ Yorùbá jẹ ona méjì, àní àwọn kàn tí wọn jẹ òrìsà funfun (White) àwọn òrìṣà yìí ni àmọ́ sì ‘tútù’ (Cold) wọn ní ìwà ìtẹríba (Humility ) ará wọn sí balẹ̀ (Balẹ̀ ). Àwọn òrìṣà kejì ni òrìṣà dúdú (Black) tàbí púpa (Red) , àwon wọ̀nyí ni wọnyi ni àmọ́ sì ‘gbígbóná’ (Hot) wọn ní agbára (Mighty), agídí (Stuborn), ìgbónára (Harsh), àti wípé ìbínú (Anger) wọn ní agbára púpọ̀.
Gẹgẹbi ènìyàn àwọn òrìṣà náà ni irufẹ oúnjẹ (Food) tí wọn nífẹ̀ẹ́, àti ohun miran ti wọn nifèsì.
Àpẹẹrẹ àwọn òrìṣà ní ilẹ Yorùbá ni
Aganju, Ajaka, Àyàngalu, Ará, Bàbáluaye, Ègúngùn, Erinlè, Èṣù, Ìbejì, Ìrókò, Ìyá ńlá, Logunede, Moremi, Ọba, Ọbatala, Odùduwà, Ogún, Òkè, Oko, Olókun, Olúmọ, Ọranyan, Oró, Orunmila, Orí, Ọ̀sanyìn, Oṣùn, Oṣùmare, Ọya, Ṣàngo àti Iyèmẹja.
Àpẹẹrẹ ńlá ni ilẹ̀ Yorùbá ni Ṣángo ọkọ Ọya
Ṣángo jẹ ọkan gbòógì nínú àwọn òrìṣà àsi tún rí ní àkọlé wípé òhun ni alágbára julọ (Most powerful) nínú àwọn òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá, a ó mú ìtàn rẹ wà ní kíkún ní ìgbà mìran, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ Yorùbá ní wípé ikapa Ṣángo ní sísan ará (Thunder) wá nígbà tí ó bá ń bínú tàbí tí wọn ba bẹẹ lọwẹ.
Àpẹẹrẹ míràn ni olókùn èyí tí ó ṣe atọ́kun Ajé wá sí ilè àyè, òrìṣà ajé jẹ́ òrìṣà tí gbogbo ènìyàn nifẹ si lọpọlọpọ tó sì fi ìsàlè omi òkun ṣé ibùgbé. Olókùn jẹ òrìṣà tí ó ikápá ìdarí òkun ń bẹ lọ́wọ́ rẹ. Gẹ́gẹ́bi òrìṣà
ajé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn féràn olókùn náà nítorí wípé ohùn náà a máa fúnni ní owó, ọmọ àlàáfíà àti àìkú baálẹ ọ̀rọ̀. A ó mú ìtàn òrìṣà kàn kàn wá ní kíkún fún àǹfààní àwa ọmọ Yorùbá ni ọjọ iwájú.
Àṣẹ (Divine Force)
Àṣẹ jẹ agbára ayé tí Yorùbá ni igbagbo wípé láti àrà rẹ láti dá gbogbo ń kán, ohun abẹmi àti bọrọgidi, wọn fi ìdí rẹ múlẹ̀ wípé àṣẹ ni ohùn tí òun jẹ́ kí ohùn gbogbo di ṣíṣe. Àṣẹ jẹ ohùn tó nííṣe pẹlu àṣà Yorùbá, àṣẹ jẹ ohùn tí ń fi ẹ̀dá láyà balẹ, ó sì tún jé ohùn ti oúnjẹ kí èròngba ẹ̀dá wá sí ìmúṣẹ. Àṣẹ jẹ́ ọna ti afi n bẹ Olódùmarè a sì tún má fi ń kí ará wá pelu, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jé ohùn tí àfi dàgbà sókè nínú ẹ̀mí.
Àwọn abọ̀rìṣà má ń dù láti ní ohùn àṣẹ láti àrà ìwà-pẹ̀lẹ́, èyí jẹ ohùn tí wọn a máa bọ ori wọn láti dì ẹni àṣẹ. Àṣẹ jẹ́ ohùn àgbàrá ńlá kàn tí ó wà láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dà ọrùn àti ayé àti gbogbo ohun tí ń bẹ láàárín méjèèjì, ó sì fi àṣẹ náà yí oòrùn ká. Láìsí oòrùn kólée sì èmi kan lórí ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ wípé láìsí àṣẹ kò leè sì èmi kan lórí ilẹ̀ ayé.
Nígbà miran àṣẹ yíò máa bẹ pẹ̀lú èṣù ọkàn lára àwọn òrìṣà. Àwọn abọ̀rìṣà ni igbagbo wípé àṣẹ ni ohun tí ó só elédùmarè, òrìṣà àti àwọn bàbà ńlá wa pọ pẹ̀lú.
We have some interesting reads that you might be interested in. Check out: The ancient orishasThe seven powers of Yoruba religion
If you would like to learn more about the Yoruba people, Read here
Àwọn Itọkasi
Falola, Toyin (2016). Encyclopedia of the Yoruba. Bloomington: Indiana University Press. pp. 84–85. ISBN 9780253021441.
Clark, Mary Ann (2002). “Children of Oduduwa”. Then We’ll Sing a New Song: African Influences on America’s Religious Landscape. Rowman & Littlefield Publishers. p. 93. ISBN 9781442208810.