DiscoverYoruba.com is your one-stop for embracing Yoruba culture, entertainment, and history unfolding.
About Us
Welcome to Discover Yoruba!
E kaabo sori ikanni Discover Yoruba!
I’m Hikmot Adewunmi, also known as Hakima, the face of Discover Yoruba.
Oruko mi ni Hikmot Adewunmi, tabi Hakima, Asoju ikanni Discover Yoruba.
The Discover Yoruba platform was created out of our deep love and pride for our Yoruba heritage. Our mission is to celebrate and preserve the rich culture, traditions, and language of the Yoruba people.
A dá ikani Discover Yorùbá sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ àti ìmúyangàn àṣà àti ìṣe Yorùbá.
Àfojúsùn wa ni kí a gbé èdè Yorùbá lárugẹ, kí a tunbọ jẹ kí àwọn ènìyàn mọ pe èdè, àṣà iṣẹ Yorùbá rẹwà púpọ̀.
Our Mission
Àfojúsùn Wa.
At Discover Yoruba, we aim to:
Ni ilé iṣẹ Discover Yorùbá, iṣẹ wa ree:
– Restore Value to the Yoruba Language: We are committed to ensuring the Yoruba language remains vibrant and relevant. Get ready to see content in Yoruba as we encourage our community to embrace and use our native tongue.
Kí á ṣe ìtọjú Èdè Yorùbá : A ṣetán láti sa gbogbo ipá láti ríi wípé ede Yoruba kó ipa pàtàkì ní àwùjọ. Ẹ gbaradì láti jẹ̀gbádùn èdè Yorùbá bí a ṣe máa rọ àwọn àwùjọ wa kí wọn máa gba sísọ èdè Yorùbá kí wọn máa sọ èdè Yorùbá láwùjọ.
– Promote Yoruba Culture and Traditions: We share insights into Yoruba history, traditions, and way of life, honouring our past heroes and cultural practices.
Kí a ṣe ìgbélárugẹ èdè àti àṣà Yorùbá : A ó máa tú èdè, àṣà, ìtàn àti ìṣe Yorùbá palẹ̀. A máa bu ọlá fún àwọn akíkanjú ọmọ àti àṣà Yorùbá.
– Highlight Yoruba Cuisine and Wellness: As a Food Science specialist with a Master’s degree from the University of Helsinki, I integrate my expertise to explore the nutritional and cultural significance of Yoruba foods. We offer general recipes, cooking tips, as well as other cuisines and wellness advice rooted in our heritage.
A má ṣe àfihàn àǹfààní àwọn oúnjẹ àti ìgbé ayé àlàáfíà. Gẹgẹ bí akọṣẹmọṣẹ onímọ̀ lẹka sise oúnjẹ ní ilé ẹ̀kọ Fafiti Helsinki, Má ṣe àmúlò ìrírí láti tọ̀nà wo àwọn oúnjẹ aṣaraloore àti àṣà pàtàkì síse oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá. A ń pèsè àwọn èròjà oúnjẹ ti o gbajugbaja, àwọn ìlànà síse oúnjẹ, ati awon ounje ilu ibomiran ati kí a si maa gba àwọn ènìyàn nímọ̀ràn nípa ìgbé ayé àlàáfíà.
– Support Yoruba Businesses: Our marketplace features products made by Yoruba artisans and businesses, promoting economic growth within our community.
Ṣíṣe iranwọ fún àwọn Okòòwò ilẹ̀ Yorùbá: A ní àwọn oríṣiríṣi ǹkan èlò tí àwọn oníṣẹ ọwọ, àti àwọn olókoòwò ọmọ Yorùbá láti ṣe igbélárugẹ àti ọrọ ajé ní àdúgbò wa
Why We Launched This Website
Ìdí tí a ṣe gbé ẹ̀rọ̀ ìtàkùn àgbáyé wa jáde:
The rich culture of the Yoruba people is at risk of being overshadowed by foreign influences. We noticed a gradual decline in the appreciation and practice of our traditions. Discover Yoruba was launched to:
A ṣe àkíyèsí wípé àṣà àti èdè Yorùbá ti ó rẹwà tí ń lọ sóko ìparun nítorí pé àwọn èdè àti àṣà òkè òkun tí ń bo èdè àti àṣà Yorùbá mọlẹ̀. A ṣe àkíyèsí pé a kii ṣe àmúlò àṣà àti èdè Yorùbá mọ.
– Remind all Yoruba people and enthusiasts to take pride in our identity.
Kí a rán àwọn ọmọ Yorùbá létí pé kí wọn máṣe gbàgbé ìpínlẹ̀ wọn.
– Educate and inspire the community to live by Yoruba principles, regardless of their background or beliefs.
Kí á kọ àwọn ènìyàn àdúgbò wa kí wọn ma ṣe àmúlò àṣà àti ìlànà Yorùbá, bí ó ti wùn kó rí
– Advocate for the continuous use and preservation of the Yoruba language.
Kí a má ṣe ìpolongo lílo èdè àti ṣíṣe apọnle èdè Yorùbá.
– Showcase and support small businesses owned by Yoruba people, both locally and globally.
Kí a máa ran àwọn olókoòwò kéréjekéréje tí àwọn ọmọ Yorùbá dá silẹ ní abẹle àti lágbàáyé.
Join Us
Discover Yoruba is more than a website; it’s a movement to reconnect with our roots and celebrate our identity. We invite you to explore, learn, and share your knowledge with us. Visit our marketplace to find unique Yoruba-made items and immerse yourself in the richness of Yoruba culture.
Ikaani ìtàkùn àgbáyé Discover Yorùbá wúlò púpọ̀: Ó jẹ́ nkan gbòógì láti mú wa padà lọ bá orírun wá, kí a jẹ ẹni tí yóò ma fi èdè, àṣà àti ìṣe Yorùbá yangàn. A ń pè yín kí ẹ wa kọ ẹ̀kọ èdè Yorùbá kí ẹ si bawa pín in jíròrò àwọn ẹ̀kọ pẹ̀lú wa. Ẹ dárapọ mọ ọjà wa kí ẹ jẹ àǹfààní àwọn ǹkan eelo Yorùbá tí wọn fọwọ ṣe. Ẹ dárapọ mọ wá ká kọ gbé èdè àti àṣà Yorùbá tó rẹwà, to kún fọfọ lárugẹ.
Together, let’s keep the Yoruba language and culture alive!
Ẹ jẹ ká pawọpọ̀ gbé èdè Yorùbá ga, kí a jẹ kí èdè Yorùbá wà láàyè!!
Hikmot Adewunmi (Hakima)
The face of Discover Yoruba