DiscoverYoruba.com is your one-stop for embracing Yoruba culture, entertainment, and history unfolding.

Àṣà Ìwọṣọ N’ílẹ̀ Yorùbá – (Yoruba clothing)

Sharing is encouraging! If you enjoy reading this article, kindly consider sharing it with your friends. Thanks!

Gẹ́gẹ́ bíi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣà àgbáyé mìíràn, àwọn Yorùbá máa ń fi aṣọ ṣe ẹ̀ṣọ́ ara àti láti dáàbò bo ara l’ọ́wọ́ èyíkéyìí irúfẹ́ ewu àyíká. Àmọ́ aṣọ ní ilẹ̀ káàrọ̀ òjííré jẹ́ ohun dídárà, tí ó ṣì jẹ̀ẹ́ kí àwọn Yorùbá yàtọ̀ sí àwọn àṣà tó kù ní àyíká wọn. Ìgbàgbọ́ wọn ní pé aṣọ wíwọ̀ ṣe àfihàn irúfẹ́ ẹni àti irú ipò tí ènìyàn ń ṣe láwùjọ, àti wípé oríṣii ìjáde ló ní aṣọ tí ẹ̀. Yorùbá fi ìyì púpọ̀ sí àṣà wíwọ aṣọ.

Yorùbá ti ń fi irun hun aṣọ kó tó d’ìgbà àwọn òyìnbó. Dídé é wọn mú kí oríṣiríṣi ohun aṣọ tó yàtọ̀ sí èyí tí àwọn baba ńlá wa fi ń ṣ’ẹ̀dá aṣọ wọ orílẹ̀-èdè wá, àmọ́ aṣọ-òkè ni gbòógì wọn ti jẹyọ. Àlàárì, sányán àti ẹtù jẹ́ oríṣiríṣi aṣọ-òkè pẹ̀lú àwọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Òfì, àrán, àdìre, àǹkará, léèsì, jàkáádì, alágbàá, gínnì ati dàmáàskì jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn ohun èlò aṣọ tó bá ìgbà dé, tí àwọn Yorùbá ń lò láti dá aṣọ.

 

oríṣìí aṣọ-òkè: àlàárì, sányán, ẹtù

Àwọn oríṣìí aṣọ-òkè: àlàárì, sányán àti ẹtù (àwòrán láti urbanstax.com àti etsy.com)

Ní òde-òní àwọn ìpín aṣọ Yorùbá yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù, a le pín àwọn aṣọ yìí sí ìbámu àwọn ẹ̀yà ara tí wọ́n bò. Fún orí – fìlà wà fún àwọn ọkùnrin, tí àwọn obìnrin ṣì ń wọ gèlè fún-ún. Ẹ̀wù ni orúkọ àpapọ̀ tí a fún aṣọ tí ẹyà Yorùbá ń lò láti bo apá òkè ara, láti ọrùn sí ìsàlẹ̀ dé déédé orúnkún. Aṣọ tí wọ́n fi ń bo ìsàlẹ̀ lati ìbàdí ni ṣòkòtò fún ọkùnrin àti ìró fún àwọn obìnrin. Ní ṣókí, àwọn ọkùnrin ní oríṣiríṣi aṣọ tí wọ́n lè wọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn obìnrin náà ni aṣọ tiwọn, ó ṣì jẹ́ èèwọ̀ fún ọkùnrin láti wọ aṣọ obìnrin àti ìdàkejì.

Aṣọ obìnrin kò pọ̀ bi alárà, ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ ohun tí wọn ń lòó, oríṣiríṣi ohun aṣọ ìgbàlódé, olówó ńlá ni wọ́n fi ń dá wọn. Aṣọ ìbílẹ̀ àwọn obìnrin láti ayé b’áyé ni ìró, bùbá, gèlè, pẹ̀lú ìborùn àbí ìpèlé nígbàmi. Àkànpọ̀ yìí jẹ́ èyí tíí pàṣẹ ìbọ̀wọ̀ fúnni láàrin àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin láwùjọ.

Aṣọ ìró ni aṣọ tí ó dàbí aṣọ ìdàbora. Ìyàtọ̀ tí ó wa nínú aṣọ ìró ati aṣọ ìbora ní pé pàlàbà ni àá ṣẹ́ etí aṣọ ìró ṣùgbọ́n ìṣẹ́tí ti aṣọ ìbora kì í fẹ̀. Ẹ̀wù bùbá kì í gùn ju ìsàlẹ̀ ìdodo lọ, ó má ń rí péńpé, apá a rẹ̀ a sì máa gùn dé ẹ̀bá ọrùn ọwọ́ l’ayé àtijọ́.

Gèlè ṣe pàtàkì sí obìnrin gẹ́lẹ́ bíi fìlà ṣe pàtàkì sí ọkùnrin. Gèlè ni ohun àwọ̀sórí tí àwọn obìnrin. O máa ń gùn ju ìdikù lo, bí wọ́n bá sì wée tán, wọn yóò dá àwékù rẹ̀ sí ìpàkọ́. Eléyìí tí óò bá aṣọ mu ni wọn yóò sì wé. Oríṣiríṣi àrà ni wọ́n le fi gèlè wíwé dá. Wọ́n le wé gèlè síwájú, èyí ni pé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì yóó wà níwájú. Wọ́n tún le wé e sí ẹ̀yìn. Nígbà mìíràn wọ́n le wé gèlè, kí wọ́n sì parí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ẹ̀gbẹ́. Ara oge ṣíṣe ni àrà tí wọ́n ń fi gèlè wíwé dá. Ki ó sì le tó wé, a máa ní aṣọ àlàkún, àwọn aránṣọ ló má ń rán-an.

Lèyìn eléyìí, wọn má ń fi ìborùn tàbí ìpèlé ṣ’àfikún ẹ̀ṣọ́ nígbàmi. Wọ́n jẹ́ abala aṣọ pàlàbà (tí kò tóbi tó ìró) pẹ̀lú ohùn aṣọ bíi tíí ìró àti bùbá. Díẹ̀ ní wọn má ń fí ju ìbàdí lọ níwájú àti ẹ̀yìn, lẹyìn ìgbà tí wọ́n bá sọ ọ́ s’èjìká.

 

Ìró, bùbá, gel̀è àti ìpèlé

Ìró, bùbá, gel̀è àti ìpèlé (àwòrán láti nairaland.com)

Aṣọ àwọn ọkùnrin pọ̀ jaburata. Àṣà ọkùnrin ni láti wọ ẹwù àwọ̀tẹ́lẹ̀ bíi bùbá, kafutáànì, dànsíkí, ẹsikí ati sapara sí abẹ́ àwọn ẹwù àwọ̀sókè ńlá. Bùbá jẹ́ aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ tó jẹ́ kòṣeémáàní fún ọmọ oòduà gidi. Aṣọ yìí jẹ́ òkan tó wọ́pọ̀ ní aṣọ akọ àti abo ní ilẹ̀ Yorùbá lápapọ̀. Bùbá okùnrin lè jẹ́ alapá tínrín, gígùn tàbí péńpé, tí ìwọ̀n rẹ̀ má ń dá lórí bí ẹni ṣe tóbi sí, àti gígùn tí kò ju orúnkún lọ. A lè fi àpò àyà àbí àpò ẹ́gbẹ̀ méjì s’ọ̀ṣọ́ bùbá.

Kafutáànì dàbi bùbá ṣùgbọ́n pẹ̀lú gigun to ju ti bùbá lọ – o ṣáábà má ń ju orúnkún lọ, apá ẹ sí jẹ eléyìí tó tínrín dé ọrùn ọwọ́. Bí wọ́n bá rii l’ọ́rùn tan, wọn yóò la á l’aya yóò fẹrẹ tó ìgbùnwọ́ kan – wọn yóò wá kó iṣẹ́ sí ọrùn àti agbègbè àyà rẹ̀ pẹ̀lú òwú fàdákà dídán àbí òwú góòlù láti mú lẹ́wà kí ó sì jojú ní gbèsè.

Dànṣíkí jẹ́ ẹwù àwọ̀télẹ́ Yorùbá tí gígùn rẹ̀ dà bí tí bùbá. Ọrùn dànsíkí lè jẹ́ ẹlẹ́ri tàbí onílílà, wọn a sì máa ṣe ọnà síi l’ọ́rùn, ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ni sìí gbé ni àpò. Bùbá àti dànsíkí jẹ́ ẹwù ti wọ́n lè ṣe ní alàwọ̀tẹ́lẹ̀ tàbí aládàánìkanwọ̀ s’óri ṣòkòtò. Fífẹ̀ àti gígùn dàǹṣíkí ayé òde-òní lo jẹ kí o tobi lati wọ nikan.

 

 

Dànṣíkí àti ̀sòkòtò kámù Dànṣíkí àti ̀sòkòtò kámù (àwòrán láti collections.artsmia.org)

Gbogbo aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ yìí ni wọn le wọ̀ sí abẹ́ àwọn aṣọ bìí agbádá, gbárìyẹ̀, dàńdóógó, ọ̀yàlà àti súlíà; àwọn aṣọ yìí la mọ̀ sí ẹ̀wù àwọ̀sókè (tàbí àwọ̀lékè).

Agbádá jẹ́ àpẹẹrẹ ẹwù pàtàkì ní àṣà Yorùbá ti wọ́n fi ọwọ́ hun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ jákàn tí a fi s’ọ̀ṣọ́ láti àyà dé ẹyìn. Ó jẹ́ ẹwù fífẹ̀ (aláìnìbámu), aláìlẹ̀gbẹ́, alápò àyà ńlá. Gígùn agbádá má ń dé kókósè, tó sì jẹ́ ẹ̀wù ti a má na wá lékè àwọn ẹ̀wù mìíràn. Bùbá, dànsíkí àbí gbárìyẹ̀ kékeré ní àwọn aṣọ tí wọ́n lè wọ̀ tẹ́lẹ̀ rẹ̀, pẹ̀lú ṣòkòtò ṣọ́rọ́ àbí kámù.

 

Agbádá àti ̀sòkòtò atú

Agbádá àti ̀sòkòtò atú (àwòrán láti collection.imamuseum.org)

Gbárìyẹ̀ rí títóbi rẹ̀ látara ọ̀pọ̀-iye awẹ́ aṣọ (ti a fi ọwọ́ hun) tí a fi rán-an, òun náà sì jẹ́ aṣọ àwọ̀sókè tí kò ní ìbámu. O jẹ́ ẹwù tí ìwọ̀n ìsàlẹ̀ rẹ̀ tóbi ju ìwọ̀n òkè-ara lọ, tí a sì máa ṣùjọ. Ṣùgbọ́n bí a bá ń rìn lọ tàbí bi a bá ń jó, ẹnu rẹ̀ tí ó ṣùjọ a máa tú, a sì máa mì rìyẹ̀. Ìdí nìyí tí a fi ń pè é ní gbárìyẹ̀ (tàbí atú). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ni wọ́n fi s’ọ̀ṣọ́ sí ara aṣọ gbárìyẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti yeti àpò méjèèjì tó wà ní iwájú, àyà, ọrùn àti ẹ̀yìn. Pẹ̀lú aṣọ òkè tó jẹ́ ohun aṣọ ìpìlẹ̀, oríṣiríṣi ẹ̀wù náà l’ó wà; a ní Gbárìyẹ̀ onígbá-awẹ́ (tí ó ní awẹ́ ọgọ́rùn-ún méjì), Gbárìyẹ̀ alápá àdán (tí àpá ẹ̀ jọ tii àdán), bẹ́ẹ̀ni a sì ní Gbárìyẹ̀ alápá àpò. Ní ayé òde-òní, wọ́n le rán Gbárìyẹ̀ kéré tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi ṣe wọ̀ nìkan àbí sí abẹ́ agbádá. Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá wọ̀ bíi àwọ̀sókè, dàǹṣíkí ló lo fún àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀.

 

Gbárìyẹ̀ àti ̀sòkòtò atú

Gbárìyẹ̀ àti ̀sòkòtò atú (àwòrán láti collection.imamuseum.org)

Dàńdóógó, tó túnmọ̀ sí ‘ọmọ gíga’ lédè Haúsá, jẹ́ aṣọ tó yàtọ̀ pẹ̀lú títóbi rẹ̀. Rírán (àti àpò) rẹ̀ dàbí tii gbárìyẹ̀ ṣùgbọ́n apá rẹ̀ dàbí tii agbádá. Nitori eléyìí ni àwọn kan fi má ń ṣìí mu sí agbádá. Ẹtí àpò ati ọrùn (n’iwájú àti ẹyìn) ni wọ́n má ń kò iṣẹ́ sí l’ọ́pọ̀lọpọ̀. L’áyé àtijọ́, aṣọ òfì olówó iyebíye bíi àlàárì àti sányán ni àá fi rán iru aṣọ báyìí, ìdí sì nì yíí tí wọ́n fi ń sọ pé ‘Dàńdógó rékọjá aṣọ tí a lè bínú dá’. Àwọn yòókù bíi alágbàá, gínnì, dàmáàskì àti àrán jẹ́ ohùn aṣọ olówó ńlá tó má ń b’uyì kún àwọn àwọ̀sókè ńlá yìí nígbà ìṣàkóso ìjọba Gẹ̀ẹ́sì, tí wọ́n sì má ń wọ̀ wọ́n fún àṣeyẹ pàtàkì. Ṣòkòtò tó bá mu nkámùmu àbí atu.

 

Dàńdóógó

Dàńdóógó (àwòrán láti Metmuseum.com)

L’ápapọ̀, gbogbo àwọn ẹ̀wù àwọ̀sókè yíì ò tíì pé láì wọ̀ wọn pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti ṣòkòtò. Fún ṣòkòtò, ọkùnrin ma ń wọ kẹ̀ǹbẹ̀, gbáanu, ṣọ́rọ́, kámù, atú, ṣòkòtò ẹlẹ́mu. Gbogbo àwọn ṣòkòtò ló ní okun ti o gbé wọn dúró ní ìbàdí, àti etí ẹsẹ̀ (nígbà míì ẹ̀gbẹ́) tó kún fọ́fọ́ fún iṣẹ́. Rírán wọn má ń lọ pẹ̀lú (àwọn) ẹ̀wù òkè ara tí wọ́n wọ̀ọ́ sí. Ohun ìyàtọ̀ àárín wọn ní títóbi ẹnu ẹsẹ̀ wọn.

Ṣọ́rọ́ jẹ́ ṣòkòtò ẹlẹnu tínrín pẹ̀lú gígùn tó dé kókósẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ohun aṣọ ìgbàlódé ni wọ́n fi rán-an l’áyé òní.

Ṣòkòtò atú àti kèǹbẹ̀ jọ ara wọn ṣùgbọ́n kẹ̀ǹbẹ̀ gùn díẹ̀ ju atú lọ. Díẹ̀ ni atú fi kọjá orúnkún ṣùgbọ́n kẹ̀ǹbẹ̀ le fẹ́rẹ̀ dé kókósẹ̀. Àwọn méjèèjì lo fẹ̀ ní ìsàlẹ̀. Atú fẹ̀ díẹ̀ lẹ́nu ju kẹ̀ǹbẹ̀ lo. Bí ènìyàn bá jókòó, ó ṣe é ṣe fún ẹni tó bọ atú ki ó mu ẹnu rẹ̀ kí ó sì fi nu ojú nù bí ò bá ń làágùn. Ìdí nìyí tí àwọn mìíràn fi ń pe ṣòkòtò atú ní àbùnujú. Wọ́n má ń wo ṣòkòtò atú àti kẹ̀ǹbẹ̀ sí ẹ̀wù Dàńdóógó, ẹ̀wù àgbàdá àti gbárìyẹ̀.

Kámù (tàbí ṣọ́rọ́ńkàmù) tóbi ní abala ìdí dé orúnkún, kí ó tó máa tínrín lo sí kókósẹ̀. Títóbi apá òkè rẹ̀ mú ki àwọn kan méfò pé ohun aṣọ ẹ̀sẹ̀ kan tóó rán ṣòkòtò Ṣọ́rọ́ kan.

O ṣòro láti s’ọ̀rọ̀ aṣọ ọkùnrin láì s’ọ̀rọ̀ fìlà. Fìlà tí àwọn Yorùbá má ń wọ̀ ò mọ sórí ìkọ̀rì, gọ̀bì, abetí-ajá, onídẹ, bẹntigọ́ọ̀, onídẹ àti lábàǹkàdà. Fìlà gọ̀bì rí rubutu, tí gígẹ̀ rẹ̀ le jẹ́ iwájú, ẹ̀yìn àbí ẹ̀gbẹ́. Orúkọ abetí-ajá ti ṣe àfihàn irú fìlà tíí ṣe. Nígbà òtútù, ó ṣeé fi bo etí. Lábàǹkàdà (tàbí Yọtí) jẹ́ ẹ̀yà abetí-ajá tó tóbi. Abẹ́ gbọ́dọ̀ wà níbi etí rẹ̀ méjèèjì. Wọ́n má ń dé fìlà yìí ní ọnà tí etí rẹ̀ ó ta s’ókè, tí yóò ṣe àfihàn àwọ aṣọ tó wà ní abẹ́ rẹ̀.

Ìrínisí ni ìsọni lọ̀jọ̀, bí a ti rìn ni à á ko’ni. Èyí ló d’ifá fún ìgbìyànjú àwọn Yorùbá láti tún ara ṣe, láti má rìnrìn ìdọ̀tí, kí olúwarẹ̀ lè ṣe é rí l’áwujo. Yorùbá tí ń wọ aṣọ oríṣiríṣi kí àwọn àjòjì tàbí òyìnbó tó dé ilẹ̀ wa, bẹẹ sì ni wọn kò wo àṣà ẹnìkan bẹ̀rẹ̀ aṣọ lílò, t’okùnrin t’obìnrin. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣọ wọ̀nyí ì ni o tí n bá ìgbà lọ, wọ́n sì ti fi àṣà ati ìṣe ẹ̀yà míìràn rọ́pò tiwọn. Ṣẹ̀bí àwọn ní wọ́n wípé; odò kì í sàn kó gbàgbé orìsun ni?

 

 

Sharing is encouraging! If you enjoy reading this article, kindly consider sharing it with your friends. Thanks!

2 Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *